Hymn 802 – AWA Egbe Omo Ogun, Kristi | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "AWA Egbe Omo Ogun, Kristi" (C&S Hymn #802, Yoruba). AWA Ẹgbẹ Ọmọ Ogun, Kristi, A tun de lati f'ogo Ọlọrun wa han, Fun…

Hymn 802 – AWA Egbe Omo Ogun, Kristi | C&S Yoruba Hymnary
AWA Ẹgbẹ Ọmọ Ogun, Kristi, A tun de lati f'ogo Ọlọrun wa han, Fun ore isẹgun Rẹ lat'esi yi wa, A dupẹ pe ko fi wa silẹ. Haleluya, Haleluya, Ẹ ke iye s'Ọlọrun wa, Haleluya, Haleluya, Aleluya, Amin. Ẹyin Ọmọ Ogun, ẹ kun f'ayọ loni, F'ohun ti Jesu Olugbala se fun wa, Ẹni t'o yan lati se ọmọ ogun Rẹ, O si tun f'agbara Rẹ wo wa. Ẹ gbe ida 'sẹgun soke, S'esu, ẹsẹ t'o n gbogun, Awa y'o ja, a o sẹgun, Alleluyah, Amin. Ọmọ Ogun, ẹ damure yin giri, Isẹ po t'a o se fun Jesu Oluwa, K'a mase r'ẹni ti esu y'o fa sẹhin, A ti sọ agbara yin d'ọtun. Ẹ ke Hosannah s'Ọba wa, Ogo ni fun orukọ RẸ, Haleluya, awa dupẹ, Ọba Olubori. Gbogbo ẹyin t'o n se, iyemeji, Ati awọn ti ko gbona ko tutu, Ọmọ Ogun Kristi wi fun yin loni, Tujuka, Jesu ti ba wa sẹgun Ẹ yọ, ẹ ke Haleluya, Iyin f'Ọlọrun wa, Ọba Adani-ma gbagbe, Haleluya, Amin. Ajẹ t'o ba ko lati ronupiwada, T'o n leri pe ko si'ru oun l'ayé, K'o lo ranti 'yalode wọn Jesibeli, Ẹni t'aja j'oku rẹ n'ita. Emi esu ẹ parada, Niwaju Ọmọgun Jesu, Awa Ọmọ Ogun Kristi, Ko ni f'esu l'aye. Ẹni t'o ba fẹ lati se'fẹ Oluwa, K'o kọ esu ati gbogbo 'se rẹ silẹ, K'o ke pe Ọlọrun Ọmọgun Kristi, Yoo gbọ y'o si ba sẹgun. Haleluya, eyi daju, Alanu l'Ọlọrun wa, Ki 'wọ sa ti le gbọran sa, Haleluya, Amin. Gbogbo ẹyin onile at'alejo, Ẹ jẹ k'a f'ogo f'Ọlọrun Ẹlẹda wa, Ọba Airi, Aiku, Ẹniyanu, Kabiyesi, awa juba Rẹ. Haleluya, awa dupẹ, Fun ibukun ọjọ oni, Haleluya, Haleluya, Haleluya, Amin. AMIN Haleluya, awa dupẹ, Fun ibukun ọjọ oni, Haleluya, Haleluya, Haleluya, Amin.

Hymn 802 – AWA Egbe Omo Ogun, Kristi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia