Hymn 794 – YIKA or'ite Olorun | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "YIKA or'ite Olorun" (C&S Hymn #794, Yoruba). YIKA or'itẹ Ọlọrun, Ẹgbẹrun ewe wa; Ewe t'a dari ẹsẹ ji, Awọn ẹgbẹ mimọ;…
YIKA or'itẹ Ọlọrun, Ẹgbẹrun ewe wa; Ewe t'a dari ẹsẹ ji, Awọn ẹgbẹ mimọ; Ń kọrin Ogo, ogo, ogo. Wo! olukuluku wọn wo, Asọ ala mimọ; Ninu imọlẹ ailopin, At'ayọ ti ki sa, Ń kọrin Ogo, ogo, ogo. Ki l'o mu wọn de ayé na, Orun t'o se mimọ, Nib' alafia at'ayọ, Bi wọn ti se de 'bẹ? Ń kọrin Ogo, ogo, ogo. Nitori Jesu ta 'jẹ Rẹ, Lati k'ẹsẹ wọn lọ; A ri wọn ninu ẹjẹ na, Wọn di mimọ laulau; Ń kọrin Ogo, ogo, ogo. L'ayé, wọn wa Olugbala, Wọn fẹ orukọ Rẹ; Nisinsin yi wọn r'oju Rẹ, Wọn wa niwaju Rẹ; Ń kọrin Ogo, ogo, ogo. Orisun na ha n san loni? Jesu, mu wa de 'bẹ; K'a le ri awọn mimọ na, K'a si ba wọn yin Ọ, Ń kọrin Ogo, ogo, ogo. AMIN
Hymn 794 – YIKA or'ite Olorun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia