Hymn 795 – AWA fe ohun aye yi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "AWA fe ohun aye yi" (C&S Hymn #795, Yoruba). ÀWA fẹ ohun ayé yi, Wọn dara l'oju wa; A fẹ k'a duro pẹ titi, Laifi wọn…
ÀWA fẹ ohun ayé yi, Wọn dara l'oju wa; A fẹ k'a duro pẹ titi, Laifi wọn silẹ lọ. Nitori kini a n se bẹ? Ayé kan wa loke; Nibẹ l'ẹsẹ oun buburu Ati ewu ko si. Ayé t'o wa loke ọrun, Awa iba jẹ mọ! Ayọ, ifẹ inu rere, Gbogbo rẹ wa n'bẹ. Iku, o wa ni ayé yi; Ko si loke ọrun; Eniyan Ọlọrun wa mbẹ, Ni aye, ni aiku. K'a ba ọna ti Jesu lọ, Eyi t'O la fun wa; Sibi rere, sibi 'sinmi, S'ile Ọlọrun wa. AMIN
Hymn 795 – AWA fe ohun aye yi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia