Hymn 789 – IBUKUN ni fun agbara | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "IBUKUN ni fun agbara" (C&S Hymn #789, Yoruba). IBUKUN ni fun agbara, Ododo oun Ọgbọn, At' Ore-ọfẹ t'o papọ, S'Isẹ…
IBUKUN ni fun agbara, Ododo oun Ọgbọn, At' Ore-ọfẹ t'o papọ, S'Isẹ Igbala wa. Baba wa j'eso-'gi aijẹ, Ogo Rẹ si wọ ‘mi; Awa ọmọ re d'ẹru, Esu ati Iku. Ọpẹ fun Baba t'O f'Ọmọ, Rẹ kansoso fun wa Ẹni t'O ku, k'awa le ye, Ka le d'ọm' Ọlọrun. Ofin Baba gbogbo t'a ru, L'ọmọ ti a pa mọ; O ku lori agbelebu; Nitori ẹsẹ wa. Wo! O ji dide n'iboji, O si goke r'ọrun, Nibẹ ni O n f'Itoye Rẹ, Gba gbogb' arufin la O gunwa lor' itẹ ogo, Pẹlu agbara nla; O f'ẹwọn ide ẹsẹ ja, T'Esu ti fi de wa. O si tun mbọ wa se 'dajọ, Pẹlu ọla-nla Rẹ; Y'o pe awọn oku mimọ; Jade pẹlu ayọ. Mba le duro l'ayọ pẹlu, N'waju On'dajọ yi! Ki n si kọrin irapada, Pẹl' awọn t'a gbala. AMIN
Hymn 789 – IBUKUN ni fun agbara | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia