Hymn 790 – GBOGBO talaka ti mo mo | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "GBOGBO talaka ti mo mo" (C&S Hymn #790, Yoruba). GBOGBO talaka ti mo mọ; Wọn ti pọ n'iye to; Kini mba se f'Ọlọrun mi,…
GBOGBO talaka ti mo mọ; Wọn ti pọ n'iye to; Kini mba se f'Ọlọrun mi, Fun gbogbo ẹbun Rẹ? Mo san j'awọn ẹlomi ni? T'Ọlọrun se n kẹ mi? Awọn ti n kiri, ti n sagbe, Lati ilé dé'lé? Alakisa ọmọ melo, Ni mbẹ l'otutu yi? 'Gba t'a fi aso wo mi, Lat' ori d'ẹsẹ mi. 'Gba awọn mi se alairi, Ibi gb'ori won le! Emi ni ile lati gbe, Ati 'bukun rere. 'Gbat' awọn mi, ti wọn n purọ, Ti n jale, ti n bura; Ni mo ti kọ ibẹru Rẹ, Lati igba ewe mi Sa wo, bi oju rere Rẹ, S'emi nikan ti pọ; Njẹ o yẹ ki n fẹ Ọ pupọ, Ki n ma sin Ọ rere? AMIN
Hymn 790 – GBOGBO talaka ti mo mo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia