Hymn 788 – OGO OBA wa ti po to | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OGO OBA wa ti po to" (C&S Hymn #788, Yoruba). OGO ỌBA wa ti pọ to, Ti mbẹ l'oke ọrun, Ọmọ-kekere wo l'o le, Kọrin ọla…
OGO ỌBA wa ti pọ to, Ti mbẹ l'oke ọrun, Ọmọ-kekere wo l'o le, Kọrin ọla 'nla Rẹ. Ta l'o le rohin ipa Rẹ, At' ore-ọfẹ Rẹ, Ko s'ẹnikan l'ayé l'ọrun, T'o mọ titobi wọn Angẹli t'o yi Oluwa ka, Ko jẹ sọ 'tumọ rẹ, Sugbọn wọn n pa asẹ rẹ mọ, Wọn si n kọrin 'yin Rẹ Njẹ mo fẹ ma ba wọn kọrin, Ki n m'ọrẹ temi wa, Ọga-Ogo ki y'o kẹgan, Ohun orin ewe. Mura, ọkan at'ahọn mi, Lati kọrin iyin, S'Olodumare Ẹlẹda. Ayọ aw' Angeli. AMIN
Hymn 788 – OGO OBA wa ti po to | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia