Hymn 787 – E BA wa korin iyin, Haleluya | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "E BA wa korin iyin, Haleluya" (C&S Hymn #787, Yoruba). Ẹ BA wa kọrin iyin, Haleluya! Ẹ ba wa yin Ọba Ogo, To da wa si…
Ẹ BA wa kọrin iyin, Haleluya! Ẹ ba wa yin Ọba Ogo, To da wa si di oni, Haleluya! Ẹ ba wa yin Ọba Ogo. Bu s'ayọ, arakunrin, Ẹ gbe orin iyin ga, Bu s'ayọ, arabinrin, Haleluya! Ẹ wa gbe Ebenezer ro. Ẹ ba wa kọrin iyin, Haleluya! Fun isẹgun t'O fi fun wa, Ti ko je k'ota yo wa, Haleluya! Ẹ ba wa yin Ọba Ogo. Bu s'ayọ, arakunrin, Ẹ gbe orin iyin ga, Bu s'ayọ, arabinrin, Haleluya! Ẹ wa gbe Ebenezer ro. Ẹ ba wa kọrin iyin, Haleluya! Fun 'sẹ 'yanu to se larin wa, To fọ itẹgun Esu, Haleluya! T'o mu wa la 'danwo kọja. Bu s'ayọ, arakunrin, Ẹ gbe orin iyin ga, Bu s'ayọ, arabinrin, Haleluya! Ẹ wa gbe Ebenezer ro. Ẹ ba wa kọrin iyin, Haleluya! Fun idagbasoke ẹmi wa, To pe wa sinu agbo, Haleluya! Ti ko jẹ ka d'ẹni gbajare. Bu s'ayọ, arakunrin, Ẹ gbe orin iyin ga, Bu s'ayọ, arabinrin, Haleluya! Ẹ wa gbe Ebenezer ro. Iyin f'Ọlọrun Baba, Haleluya! Iyin fun Ọlọrun Ọmọ, Iyin fun Ẹmi Mimọ , Haleluya! Mẹtalọkan la fi 'yin fun. Bu s'ayọ, arakunrin, Ẹ gbe orin iyin ga, Bu s'ayọ, arabinrin, Haleluya! Ẹ wa gbe Ebenezer ro. AMIN Bu s'ayọ, arakunrin, Ẹ gbe orin iyin ga, Bu s'ayọ, arabinrin, Haleluya! Ẹ wa gbe Ebenezer ro.
Hymn 787 – E BA wa korin iyin, Haleluya | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia