Hymn 786 – A DUPE lowo Olorun | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "A DUPE lowo Olorun" (C&S Hymn #786, Yoruba). A DUPẸ lọwọ Ọlọrun, T'O fi Jesu Kristi fun wa; Lati ra arayé pada, Lọwọ…
A DUPẸ lọwọ Ọlọrun, T'O fi Jesu Kristi fun wa; Lati ra arayé pada, Lọwọ ẹsẹ ati esu. Ẹ yin logo, ẹ f'ọpẹ fun, Ọlọrun Mẹtalọkan; Fun anu at'ore Rẹ; Lori gbogbo Ẹgbẹ Séráfù. Agbara Ọlọrun n dagba, Ogo Jesu n han si wa, Agbara Ẹmi Mimọ wa, Larin Ijọ Séráfù. Ẹ yin logo, ẹ f'ọpẹ fun, Ọlọrun Mẹtalọkan; Fun anu at'ore Rẹ; Lori gbogbo Ẹgbẹ Séráfù. Gbogbo eniyan at'orilẹ-ede, Dorikodo s'adura, Ẹ yipada l'emi otọ, Ki Baba ọrun gba wa. Ẹ yin logo, ẹ f'ọpẹ fun, Ọlọrun Mẹtalọkan; Fun anu at'ore Rẹ; Lori gbogbo Ẹgbẹ Séráfù. Ẹsẹ pọ, ayé yi daru, Esu n jale, o si n yọ, K'onigbagbọ pe adura pọ, K'a le sẹgun ẹsẹ at'esu. Ẹ yin logo, ẹ f'ọpẹ fun, Ọlọrun Mẹtalọkan; Fun anu at'ore Rẹ; Lori gbogbo Ẹgbẹ Séráfù. Olufọkansin onigbagbọ, Jesu mọ ise ikọkọ rẹ; Mase lọ, l'ohun Oluwa n wi, Olukọ re n sunmọle, Ẹ yin logo, ẹ f'ọpẹ fun, Ọlọrun Mẹtalọkan; Fun anu at'ore Rẹ; Lori gbogbo Ẹgbẹ Séráfù. Kérúbù, Séráfù, mura, Alufa, Bishop, mura, Ẹyin to mọ Jesu, ẹ mura, Lọjọ 'kẹhin ọjọ 'dajọ. Ẹ yin logo, ẹ f'ọpẹ fun, Ọlọrun Mẹtalọkan; Fun anu at'ore Rẹ; Lori gbogbo Ẹgbẹ Séráfù. Ajọdun miran l'awa n se, T'Ọlọrun ran Mose; Lati s'ẹgbẹ yi lorukọ, Ogun ọrun Séráfù. Ẹ yin logo, ẹ f'ọpẹ fun, Ọlọrun Mẹtalọkan; Fun anu at'ore Rẹ; Lori gbogbo Ẹgbẹ Séráfù. Ẹgbẹ Mose, ẹ mura dide, Larin Ijọ Kérúbù, Séráfù; Ọlọrun Baba lo fun wa, Gbe asia rẹ soke. Ẹ yin logo, ẹ f'ọpẹ fun, Ọlọrun Mẹtalọkan; Fun anu at'ore Rẹ; Lori gbogbo Ẹgbẹ Séráfù. Keferi, Imale, e wa, Onigbagbọ, ẹ ma kalọ, Ka jọ yin Ọlọrun logo, Ka le gba ade iye, Ẹ yin logo, ẹ f'ọpẹ fun, Ọlọrun Mẹtalọkan; Fun anu at'ore Rẹ; Lori gbogbo Ẹgbẹ Séráfù. Ọlọrun Baba sanu wa, Dariji wa, pa wa mọ, Ran wa lọwọ, gbadura wa, Titi ayé ainipẹkun. Ẹ yin logo, ẹ f'ọpẹ fun, Ọlọrun Mẹtalọkan; Fun anu at'ore Rẹ; Lori gbogbo Ijọ Séráfù. AMIN Ẹ yin logo, ẹ f'ọpẹ fun, Ọlọrun Mẹtalọkan; Fun anu at'ore Rẹ; Lori gbogbo Ijọ Séráfù.
Hymn 786 – A DUPE lowo Olorun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia