Hymn 785 – IYIN f'Eni Mimo julo | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "IYIN f'Eni Mimo julo" (C&S Hymn #785, Yoruba). IYIN f'Ẹni Mimọ julọ, Loke ati n'ilẹ, Ọrọ Rẹ gbogbo jẹ 'yanu, Gbogb'…
IYIN f'Ẹni Mimọ julọ, Loke ati n'ilẹ, Ọrọ Rẹ gbogbo jẹ 'yanu, Gbogb' ọna rẹ daju. Ọgbọn Ọlọrun ti pọ to! 'Gbat' eniyan subu; Adam keji wa s' oju ja, Ati lati gbala. Ọgbọn ifẹ! p'ẹran ara T'o gbe Adam subu, Tun b' ọta ja ija ọtun, K'o ja k'o si sẹgun. Ati p'ẹbun t'o j' or' ọfẹ Sọ ara di ọtun; Ọlọrun papa Tikarẹ, J'Ọlọrun ninu wa. Ifẹ 'yanu! ti Ẹni ti, O pa ọta eniyan, Ninu awọn awa eniyan, Jẹ irora f'eniyan. Nikọkọ ninu ọgba ni, Ati l'ori igi, T'o si kọ wa lati jiya, To kọ wa lati ku. Iyin f'Ẹni Mimọ julọ, L'oke ati n'ilẹ; Ọrọ Rẹ gbogbo jẹ 'yanu, Gbogb' ọna Rẹ daju. AMIN
Hymn 785 – IYIN f'Eni Mimo julo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia