Hymn 784 – OLODUMARE a juba | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OLODUMARE a juba" (C&S Hymn #784, Yoruba). OLODUMARE a juba ) A ke saki si Ọ baba )2 Kérúbù pẹlu Séráfù tayé)2 A jẹwọ,…
OLODUMARE a juba ) A ke saki si Ọ baba )2 Kérúbù pẹlu Séráfù tayé)2 A jẹwọ, a si juba Rẹ, Olubukun, Sẹr' ibukun Rẹ sori wa. Ọbangiji a dupẹ o ) Fun iranti Rẹ lori wa )2ce Ojojumọ l'a n ri 'ranlọwọ rẹ)2 O n sikẹ, O si n tọju wa nigba-kugba, Baba, mase fi wa silẹ. Mẹtalọkan a juba o ) Baba, Ọmọ, Ẹmi-Mimọ )2ce Baba wa Olore-ọfẹ julọ)2ce Wọn n'iyin ati ọpẹ yẹ fun titi; Tẹwọ gba iyin, ọpẹ wa. Jah Jehovah, a sọpẹ o ) Jehofa Nissi Baba wa, )2ce K'O da gbogbo ọmọ ẹgbẹ yi si; Ka ma ri gbami-gbami at' akowaba, Ka ma ri agbako ayé. Olupese, a dupẹ o ) Jehovah Jire Ọba wa ) 2ce 'Wọ lo n pese fun gbogbo aini wa, A ri ore-ọfẹ Rẹ gba lojojumọ, A dupẹ a t'ọpẹ da. Olugbala, a juba o, ) Iwọ lo d'ẹgbẹ yi silẹ, )2ce Ma jẹ ki fitila Ẹgbẹ yi ku,)2 Ran wa lọwọ k'a le mase ifẹ Rẹ, Titi ayé ainipẹkun AMIN
Hymn 784 – OLODUMARE a juba | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia