Hymn 783 – E WOLE f'Oba wa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "E WOLE f'Oba wa" (C&S Hymn #783, Yoruba). Ẹ WOLẸ f'Ọba wa, Ọmọ Mimọ Baba, Ẹlẹda, Alabo, Olugbala gbogbo arayé. Gbogbo…
Ẹ WOLẸ f'Ọba wa, Ọmọ Mimọ Baba, Ẹlẹda, Alabo, Olugbala gbogbo arayé. Gbogbo ayé, ẹ fori balẹ f'Olodumare, Ẹni t'o ra wa pada, Aleluja gb'orin sẹgun naa ga; Mẹtalọkan wa l'Ọba ogo. Mi si wa, Oluwa, Ka pin n'nu ogo Rẹ; Orisun iye wa, Ato-bajayé Ọba ogo. Gbogbo ayé, ẹ fori balẹ f'Olodumare, Ẹni t'o ra wa pada, Aleluja gb'orin sẹgun naa ga; Mẹtalọkan wa l'Ọba ogo. Ayé pẹl' ẹkun rẹ, Tirẹ ni Oluwa Awọn to gba Ọ gbọ, Ni yoo jogun Rẹ titi ayé. Gbogbo ayé, ẹ fori balẹ f'Olodumare, Ẹni t'o ra wa pada, Aleluja gb'orin sẹgun naa ga; Mẹtalọkan wa l'Ọba ogo. Ikore ayé gbọ, Ẹ mura, arayé, Olukore fẹrẹ de, Alikama nikan ni Tirẹ Gbogbo ayé, ẹ fori balẹ f'Olodumare, Ẹni t'o ra wa pada, Aleluja gb'orin sẹgun naa ga; Mẹtalọkan wa l'Ọba ogo. Lọjọ ifarahan, Jẹwọ mi, Oluwa; Jẹk' ore-ọfẹ Rẹ, Mu wa yẹ lati ba Ọ gunwa. Gbogbo ayé, ẹ fori balẹ f'Olodumare, Ẹni t'o ra wa pada, Aleluja gb'orin sẹgun naa ga; Mẹtalọkan wa l'Ọba ogo. AMIN Gbogbo ayé, ẹ fori balẹ f'Olodumare, Ẹni t'o ra wa pada, Aleluja gb'orin sẹgun naa ga; Mẹtalọkan wa l'Ọba ogo.
Hymn 783 – E WOLE f'Oba wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia