Hymn 782 – WA, Jesu fi ara han | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "WA, Jesu fi ara han" (C&S Hymn #782, Yoruba). WA, Jesu fi ara han, Wa, jẹ k'ọkan wa mọ Ọ, Wa, mu gbogb' ọkan gbona,…

Hymn 782 – WA, Jesu fi ara han | C&S Yoruba Hymnary
WA, Jesu fi ara han, Wa, jẹ k'ọkan wa mọ Ọ, Wa, mu gbogb' ọkan gbona, Wa, bukun wa k'a to lọ. Wa, f'aya wa n'isinmi, Wa, k'a d'alabukun fun, Wa, sọrọ alafia, Wa busi igbagbọ wa. Wa, le 'siyemeji lọ, Wa, ko wa b'a ti bẹbẹ; Wa, fun ọkan wa n'ifẹ, Wa, fa ọkan wa soke. Wa, sọ f'ọkan wa k'o yọ, Wa, wi pé ―Wo ni mo yan,‖ Wa, p'awọn agbo Rẹ mọ, Wa sure f'aguntan Rẹ. AMIN

Hymn 782 – WA, Jesu fi ara han | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia