Hymn 781 – SURE fun wa loni, Baba orun | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "SURE fun wa loni, Baba orun" (C&S Hymn #781, Yoruba). SURE fun wa loni, Baba ọrun, A gboju wa soke si Ọ, 'Wọ to sure…

Hymn 781 – SURE fun wa loni, Baba orun | C&S Yoruba Hymnary
SURE fun wa loni, Baba ọrun, A gboju wa soke si Ọ, 'Wọ to sure f'Abraham baba wa, Jọwọ sure fun wa. Alpha ati Omega, A si ọkan wa paya fun Ọ, Ma jẹ ka lọ lofo. Mẹtalọkan Mimọ Alagbara, Ifẹ to jinlẹ julọ; Awamaridi Olodumare, Jọ f'ire kari wa. Alpha ati Omega, A si ọkan wa paya fun Ọ, Ma jẹ ka lọ lofo. Awa n ke pe Ọ loni, Baba wa, Ma jẹ k'ọmọ Rẹ rahun; Ko sohun ti jamọ lẹhin ẹkun, Jọwọ dabobo wa. Alpha ati Omega, A si ọkan wa paya fun Ọ, Ma jẹ ka lọ lofo. 'Wọ lo m'omi lat' inu apata, F'awọn eniyan Rẹ 'saju; O rọjo manna pẹlu lat'ọrun, Jọwọ pese fun wa. Alpha ati Omega, A si ọkan wa paya fun Ọ, Ma jẹ ka lọ lofo. AMIN Alpha ati Omega, A si ọkan wa paya fun Ọ, Ma jẹ ka lọ lofo.

Hymn 781 – SURE fun wa loni, Baba orun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia