Hymn 780 – OLORUN wa mbe larin wa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OLORUN wa mbe larin wa" (C&S Hymn #780, Yoruba). ỌLỌRUN wa mbẹ larin wa, Y'o si bukun gbogbo wa, Wo oju ọrun b'o ti…
ỌLỌRUN wa mbẹ larin wa, Y'o si bukun gbogbo wa, Wo oju ọrun b'o ti su, Yoo rọ‘jo ibukun, K'o de, Oluwa, a bẹ Ọ, Jẹ k'ojo ibukun de; Awa n duro, awa n duro, M'ọkan gbogbo wa sọji. Ọlọrun wa mbẹ larin wa, Ninu ile mimọ yi; Sugbọn a n fẹ 'tura ọkan, Ati ọpọ ore-ọfẹ. K'o de, Oluwa, a bẹ Ọ, Jẹ k'ojo ibukun de; Awa n duro, awa n duro, M'ọkan gbogbo wa sọji. Ọlọrun wa mbẹ larin wa; K'a f'ọkan 'gbagbọ bere, Ohun t'a fẹ lọwọ Rẹ, ki 'Fẹ Rẹ m'ọkan wa gbona. K'o de, Oluwa, a bẹ Ọ, Jẹ k'ojo ibukun de; Awa n duro, awa n duro, M'ọkan gbogbo wa sọji. Olugbala gb'adura wa, B'a ti f'igbagbọ kunlẹ; Jọ si ferese anu Rẹ, K'o da 'bukun sori wa. K'o de, Oluwa, a bẹ Ọ, Jẹ k'ojo ibukun de; Awa n duro, awa n duro, M'ọkan gbogbo wa sọji. AMIN K'o de, Oluwa, a bẹ Ọ, Jẹ k'ojo ibukun de; Awa n duro, awa n duro, M'ọkan gbogbo wa sọji.
Hymn 780 – OLORUN wa mbe larin wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia