Hymn 779 – OLUGBALA, a tun fe f'ohun kan | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OLUGBALA, a tun fe f'ohun kan" (C&S Hymn #779, Yoruba). OLUGBALA, a tun fẹ f'ohun kan; Yin Orukọ Rẹ ka to lọ si'le;…
OLUGBALA, a tun fẹ f'ohun kan; Yin Orukọ Rẹ ka to lọ si'le; N'ipari isin, a n tor'anu Rẹ, A o si kunlẹ fun ibukun Rẹ. F'alafia fun wa ba ti n rele, Jẹ ka pari ọjọ yi pẹlu Rẹ, Pa aya wa mọ, si sọ ete wa, T'a fi n pe orukọ Rẹ nihin yi. F'alafia fun wa loru oni, Sọ okunkun rẹ di imọlẹ fun wa; Ninu ewu yọ awa ọmọ Rẹ, Okun oun 'mọlẹ j' ọkanna fun Ọ. F'alafia fun wa lọj' ayé wa, Rẹ wa lẹkun, ko si gbe wa nija; 'Gbat' O ba si f' opin si ijamu wa, Pe wa, Baba, s'ọrun Alafia. AMIN
Hymn 779 – OLUGBALA, a tun fe f'ohun kan | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia