Hymn 078 – T'OLORUN Oluwa nile | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "T'OLORUN Oluwa nile" (C&S Hymn #078, Yoruba). 1. T'ỌLỌRUN Oluwa nilẹ, Ati gbogbo ẹkun rẹ; Ayé at'awọn eniyan, Ti o…

Hymn 078 – T'OLORUN Oluwa nile | C&S Yoruba Hymnary
1. T'ỌLỌRUN Oluwa nilẹ, Ati gbogbo ẹkun rẹ; Ayé at'awọn eniyan, Ti o tẹdo sinu rẹ. Awamaridi ni'sẹ Rẹ, Oluwa ọmọ-ogun, Ogo ọla at'agbara Ni fun Ọ Mẹtalọkan. 2. Tani yoo goke Oluwa, Ati ibi mimọ Rẹ, Ẹni t'o ni ọwọ mimọ, Ti aya rẹ si funfun. 3. Awọn ti ko gbọkan soke, S'ohun asan ayé yi, Ti ko si jẹ bura ẹtan, Yoo ri 'bukun Oluwa gba. 4. Eyi l'awọn to n safẹri, Oju Ọlọrun Jakob, Awọn to duro d'Oluwa, Ni yoo ri 'bukun gba. 5. Gbori soke ẹnu ọna, Ka si tun gbe yin soke, Ẹyin l'ẹkun ayérayé, K'Ọba Ogo le wọle. 6. Tani Ọba Ologo yi! Oluwa ọmọ ogun, Ẹni to l'agbara l'ogun, Oun ni Ọba Ogo yi. 7. Gbori soke ẹnu ọna, K'Ọba Ogo le wọle, Tani Ọba Ogo yi? Oluwa ọmọ-ogun. AMIN

Hymn 078 – T'OLORUN Oluwa nile | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia