Hymn 079 – BABA Mimo jowo sunmo wa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "BABA Mimo jowo sunmo wa" (C&S Hymn #079, Yoruba). 1. BABA Mimọ jọwọ sunmọ wa, Ọmọ Mimọ jọwọ sunmọ wa, Ẹmi Mimọ jọwọ…
1. BABA Mimọ jọwọ sunmọ wa, Ọmọ Mimọ jọwọ sunmọ wa, Ẹmi Mimọ jọwọ sunmọ wa, A sunmọ Ọ, fi 'bukun fun wa. Baba wa, Baba wa Edumare jọwọ bukun wa, Baba wa, Baba wa, Edumare jọwọ bukun wa. 2. Jehovah Jire wa ba wa pe, K'O si ma gbe inu ọkan wa, Masai f'oju anu Rẹ wo wa, Ko si f'ẹsẹ Ẹgbẹ wa mulẹ. 3. Oluwa pese Ẹmi Rẹ fun wa, Ka wa le sin Ọ titi d'opin, Ko si ma samọna Ẹgbẹ wa, Ka le fi 'jọba Rẹ s'ere jẹ. 4. Pese fun gbogbo awọn Ọmọ Ẹgbẹ, Pese isẹ f'awọn alairise, Mase jẹ ki gbogbo wa rahun, Masai fi 'bukun Rẹ kari wa. 5. Nigba t'a ba si f'ayé yi silẹ, Ka wa le jẹ ẹni 'tẹwọgba, K'awa sile ba Jesu gunwa, Niwaju itẹ Mẹtalọkan. 6. Nikẹhin k'a le gbọ ohun ni, Ẹ wa ẹyin Alabukun fun Bọ sinu ayọ Oluwa Rẹ, K'a le b'awọn Angẹl kọrin 'yin. Baba wa, Baba wa Edumare jọwọ bukun wa, Baba wa, Baba wa, Edumare jọwọ bukun wa. AMIN
Hymn 079 – BABA Mimo jowo sunmo wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia