Hymn 077 – T'OLUWA n'ile at'ekun re | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "T'OLUWA n'ile at'ekun re" (C&S Hymn #077, Yoruba). 1. T'OLUWA n'ilẹ at'ẹkun rẹ, Ayé at'ẹkun 'nu rẹ; O fi di r sọlẹ…

Hymn 077 – T'OLUWA n'ile at'ekun re | C&S Yoruba Hymnary
1. T'OLUWA n'ilẹ at'ẹkun rẹ, Ayé at'ẹkun 'nu rẹ; O fi di r sọlẹ lor'okun, Ati lori san omi Gb'ori soke, Ẹyin 'lẹkun, K'a gbe yin soke, K'Ọba Ogo wọle wa. 2. Tani yoo g'ori oke yi lọ, Ori oke Oluwa; Tani yoo duro niwaju Rẹ, Niwaju Oluwa wa. 3. Ẹni t'o ni ọwọ mimọ, T'o si ni aya funfun; Ti ko gb'ọkan rẹ s'oke s'asan, Ti ko si bura ẹtan. 4. Awa n'iran ti n s'afẹri Rẹ, Safẹri Rẹ Oluwa; Awa yoo si ri ibukun gba, Lọwọ Ọlọrun Jakob. 5. f A! Tani Ọba awọn ọba? Ti 'se Ọba Ogo yi? Oluwa awọn ọmọ-ogun, Oun naa ni Ọba Ogo. Gb'ori soke, Ẹyin 'lẹkun, K'a gbe yin soke, K'Ọba Ogo wọle wa. AMIN

Hymn 077 – T'OLUWA n'ile at'ekun re | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia