Hymn 76 – WA, Parakliti Mimo | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "WA, Parakliti Mimo" (C&S Hymn #76, Yoruba). 1. mp WA, Parakliti Mimọ, Lat' ibugbe Rẹ ọrun, Ran itansan 'mọlẹ wa, 2.…

Hymn 76 – WA, Parakliti Mimo | C&S Yoruba Hymnary
1. mp WA, Parakliti Mimọ, Lat' ibugbe Rẹ ọrun, Ran itansan 'mọlẹ wa, 2. Baba talaka, wa 'hin, Olufunni l'ẹbun wa, Imọlẹ ọkan jọ wa. 3. Baba Olutunu wa, Alejo tootọ f'ọkan, Pẹlu itura-Rẹ wa. 4. 'Wọ n'isinmi n'nu lala, Iboji ninu oorun, Itunu ninu 'pọnju. 5. 'Wọ 'mọlẹ t'o mọ gara, Tan sinu aya awọn; Eniyan Rẹ olootọ. 6. L'aisi Rẹ ki l'ẹda jẹ? Ise at'ero Mimọ, Lat'ọdọ Rẹ wa ni wọn. 7. Eleeri, sọ di mimọ, Agbọgbẹ masai wo san, Alaileso mu s'eso. 8. Mu ọkan tutu gbona, M'alagidi tẹriba, Fa asako wa jẹjẹ. 9. F'ẹmi 'jinlẹ Rẹ meje, Kun awọn olootọ Rẹ, F'agbara Rẹ s'abo wọn. 10. Ran or'ọfẹ Rẹ sihin, Ẹkun igbala layé, At'alafia l'ọrun. AMIN

Hymn 76 – WA, Parakliti Mimo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia