Hymn 769 – JESU Oluwa ni 'se | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "JESU Oluwa ni 'se" (C&S Hymn #769, Yoruba). JESU Oluwa ni 'se Ipilẹ Ijọ Rẹ; Omi ati ọrọ Rẹ, Ni Oun si fi tun da; O…

Hymn 769 – JESU Oluwa ni 'se | C&S Yoruba Hymnary
JESU Oluwa ni 'se Ipilẹ Ijọ Rẹ; Omi ati ọrọ Rẹ, Ni Oun si fi tun da; O t'ọrun wa, O fi se, Iyawo mimọ Rẹ: Ẹjẹ Rẹ l'O si fi ra, Ti O si ku fun u. N'ile gbogbo l'a sa wọn, Sugbọn wọn jẹ ọkan, Oluwa kan, 'gbagbọ kan, Ati baptisi kan; Orukọ kan ni wọn yin Ounjẹ kan ni wọn n jẹ, Opin kan ni wọn n lepa, Nipa ore-ọfẹ. Bi ayé tilẹ n kẹgan, Gba t'iyọnu de ba ; Bi 'ja oun ẹkọ-kẹ-kọọ, Ba mu iyapa wa, Awọn mimọ yoo ma ke, Wi pé y'o ti pẹ to? Oru ẹkun fẹrẹ di, Oorọ orin ayọ. L'arin gbogbo 'banujẹ, At' iyọnu ayé, O n reti ọjọ 'kẹhin, Alafia lailai; Titi y'o f'oju rẹ ri, Iran ologo na, Ti ijọ nla asẹgun, Y'o d'ijọ ti n sinmi. L'ayé, yi o ni 'dapọ, Pẹlu Mẹtalọkan! O si ni 'dapọ didun; Pẹl' awọn t'o ti sun; A! alabukun mimọ! Oluwa, fi fun wa, Ka ba le ri bi awọn, Ka ba Ọ gbe 'lọrun. AMIN

Hymn 769 – JESU Oluwa ni 'se | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia