Hymn 768 – OJO Wura oj'Olorun | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OJO Wura oj'Olorun" (C&S Hymn #768, Yoruba). ỌJỌ Wura ọj'Ọlọrun, T'ọkan aisẹ nin' ọgba na, Nib'ayọ nla ko si l'ayé,…
ỌJỌ Wura ọj'Ọlọrun, T'ọkan aisẹ nin' ọgba na, Nib'ayọ nla ko si l'ayé, 'Bi 'tura ni Paradise. Paradise …. Paradise A pẹ k'a to f'ayé silẹ Nib' imọlẹ …. Paradise, Jesu j'Ọba loke lọhun. 'Subu ara, ẹsẹ 'tiju, Iku 'dajọ, Ida jọ wọn, 'Dẹkun ẹsẹ parẹ lọhun, Ayé lọ ni Paradise, Paradise …. Paradise A pẹ k'a to f'ayé silẹ Nib' imọlẹ …. Paradise, Jesu j'Ọba loke lọhun. Ko s'adura, ko si ewu, Ko s'ẹdun mọ, ipo sofo, 'Boji ati ibanujẹ, Ko si wọn ni Paradise. Paradise …. Paradise A pẹ k'a to f'ayé silẹ Nib' imọlẹ …. Paradise, Jesu j'Ọba loke lọhun. Krist' Oluwa lori igi, Ẹlẹsẹ ke, pe ranti mi, Loni 'wọ y'o l'Oluwa wi, Pẹlu mi ni Paradise. Paradise …. Paradise A pẹ k'a to f'ayé silẹ Nib' imọlẹ …. Paradise, Jesu j'Ọba loke lọhun. Ọjọ wura, 'gba Kristi ji, 'Boji silẹ, aro si pin, Ogo nla bo, oku ji, y'o Ba jọba ni Paradise. Paradise …. Paradise A pẹ k'a to f'ayé silẹ Nib' imọlẹ …. Paradise, Jesu j'Ọba loke lọhun. Kérúbù ho, Séráfù yọ, Eyi ko ha t'ayọ rẹ bi, Pe Jesu la ọna 'gbala, Lati ayé lọ de ọrun. Paradise …. Paradise A pẹ k'a to f'ayé silẹ Nib' imọlẹ …. Paradise, Jesu j'Ọba loke lọhun. Tẹra-mọsẹ, ni ere rẹ, Lati le ri 'hin rere jẹ, K'a ma kuna Paradise, Ọpẹ ni fun Mẹtalọkan. Paradise …. Paradise A pẹ k'a to f'ayé silẹ Nib' imọlẹ …. Paradise, Jesu j'Ọba loke lọhun. AMIN Paradise …. Paradise A pẹ k'a to f'ayé silẹ Nib' imọlẹ …. Paradise, Jesu j'Ọba loke lọhun.
Hymn 768 – OJO Wura oj'Olorun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia