Hymn 767 – EGBEGBERUN aimoye | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "EGBEGBERUN aimoye" (C&S Hymn #767, Yoruba). ẸGBẸGBẸRUN aimoye, Wọn wọ asọ ala, Ogun awọn t'a rapada, Wọn kun 'bi 'mọlẹ…
ẸGBẸGBẸRUN aimoye, Wọn wọ asọ ala, Ogun awọn t'a rapada, Wọn kun 'bi 'mọlẹ na; Ija wọn pẹlu ẹsẹ; At'iku ti pari, Ẹ si 'lẹkun wura silẹ, Fun awọn asẹgun. Iro Haleluya wọn, L'o gb'ayé ọrun kan, Iro ẹgbẹgbẹrun Harpu, N dun pe 'sẹgun de tan; Ọjọ t'a s'ẹda ayé, T'a da oril'ede; Ayọ nla pa 'banujẹ rẹ, Ti a fun ni kikun. A! ayọ t'a ko le sọ, L'eti bebe Kenaan; Idapọ nla wo lo to yii, Ibi t'a ki pinya; Oju t'o kun f'ẹkun ri, Y'o tun mọ 'lẹ ayọ; Ki yoo si alaini baba, Ọpọ ki yoo si mọ. Mu igbala nla Rẹ wa, Ọd' aguntan t'a pa; Sọ 'ye awọn ayanfẹ Rẹ, Mu 'pa Rẹ k'o jọba, Wa, ifẹ oril' ede, Da onde Rẹ silẹ, Wa fi ami 'leri Rẹ han, Wa, Olugbala wa. AMIN
Hymn 767 – EGBEGBERUN aimoye | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia