Hymn 770 – EYIN 'ranse Kristi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "EYIN 'ranse Kristi" (C&S Hymn #770, Yoruba). ẸYIN 'ransẹ Kristi, Gbọ ohun ipe Rẹ, Ẹ tẹle 'bi t'o fọna han, A n pe yin…
ẸYIN 'ransẹ Kristi, Gbọ ohun ipe Rẹ, Ẹ tẹle 'bi t'o fọna han, A n pe yin s'ọna Rẹ. Baba ti ẹyin n sin, O n'ipa to fun yin; N'igbẹkẹle ileri Rẹ, Ẹ ja bi ọkunrin. Lọ f'Olugbala han Ati anu nla Rẹ, F'awọn otosi ẹlẹsẹ; Ninu ọmọ Adam. L'orukọ Jesu wa, A ki yin, ―Ọna rẹ! ‖ A mbẹ Ẹni t'o ran yin lọ, K'O busi isẹ yin. AMIN
Hymn 770 – EYIN 'ranse Kristi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia