Hymn 759 – LALA alagbase tan | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "LALA alagbase tan" (C&S Hymn #759, Yoruba). LALA alagbase tan; Ọjọ ogun ti pari; L'ebute jijin rere, Ni oko rẹ ti gun…
LALA alagbase tan; Ọjọ ogun ti pari; L'ebute jijin rere, Ni oko rẹ ti gun si. Baba, labẹ itọju Rẹ, L'awa f'iransẹ Rẹ yi si. Nibẹ l'a rẹ wọn l'ẹkun; Nibẹ, wọn m'ohun gbogbo, Nibẹ l'Onidaj' otọ, N dan isẹ ayé wọn wo. Baba, labẹ itọju Rẹ, L'awa f'iransẹ Rẹ yi si. Nibẹ l'olus' aguntan, N ko awọn aguntan lọ; Nibẹ l'o n dabo bo wọn, Koriko ko le de'bẹ. Baba, labẹ itọju Rẹ, L'awa f'iransẹ Rẹ yi si. Nibẹ l'awọn ẹlẹsẹ, Ti n tẹju m'agbelebu, Y'o mọ ifẹ Kristi tan, L'ẹsẹ Rẹ ni Paradise. Baba, labẹ itọju Rẹ, L'awa f'iransẹ Rẹ yi si. Nibẹ l'agbara Esu, Ko le b'ayọ wọn jẹ mọ; Kristi Jesu a n sọ wọn; Oun t'o ku fun dande wọn. Baba, labẹ itọju Rẹ, L'awa f'iransẹ Rẹ yi si. Erupẹ fun erupẹ, L'ede wa nisinsin yi; A tẹ silẹ lati sun, Titi d'ọjọ ajinde. Baba, labẹ itọju Rẹ, L'awa f'iransẹ Rẹ yi si. AMIN Baba, labẹ itọju Rẹ, L'awa f'iransẹ Rẹ yi si.
Hymn 759 – LALA alagbase tan | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia