Hymn 760 – OLUFE, ma sun, ko si ma sinmi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OLUFE, ma sun, ko si ma sinmi" (C&S Hymn #760, Yoruba). OLUFẸ, ma sun, ko si ma sinmi, Gb'ori le aya Olugbala Rẹ, A fẹ…
OLUFẸ, ma sun, ko si ma sinmi, Gb'ori le aya Olugbala Rẹ, A fẹ ọ, sugbọn Jesu fẹ ọ ju, Sunre, Sunre, Sunre. Orun itura bi ọmọ titun, Isẹ oun ẹkun rẹ ti pari na, Sinmi l'alafia titi ayé, Sunre, Sunre, Sunre. Sinmi titi ayé ki yoo si mọ, Ti a o ko Alikama s'aba, Ti a o sun epo oun iyangbo, Sunre, Sunre, Sunre. Titi ogo ajinde yoo fi tan, Tit' awọn to ku n'nu Jesu yoo nde, Oun yoo si wa pẹlu ọlanla Rẹ Sunre, Sunre, Sunre. A o f'ifẹ Jesu se ọ logo, Wọ yoo si ji laworan Ọlọrun, Oun yoo si mu ade ogo rẹ wa, Sunre, Sunre, Sunre. Sunre, olufẹ, ki se titi lai, Lẹhin 'gba diẹ awọn ẹni mimọ, Yoo ma gbe pọ ni irẹpọ mimọ, Sunre, Sunre, Sunre. Titi a o fi pade ni itẹ Rẹ A o si wọ wa l'agbada funfun; T'a o si ri gẹgẹ b'a ti mọ wa, Sunre, Sunre, Sunre. AMIN
Hymn 760 – OLUFE, ma sun, ko si ma sinmi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia