Hymn 758 – IGBA asale ti dun to | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "IGBA asale ti dun to" (C&S Hymn #758, Yoruba). IGBA asalẹ ti dun to! Ti ara tu ohun gbogbo; 'Gbat' itansan orun alẹ,…

Hymn 758 – IGBA asale ti dun to | C&S Yoruba Hymnary
IGBA asalẹ ti dun to! Ti ara tu ohun gbogbo; 'Gbat' itansan orun alẹ, Ba n tan‘mọlẹ s'ohun gbogbo. Bẹni 'kẹhin onigbagbọ, Oun a sinmi l'alafia; Igbagbọ t'o gbona janjan, A mọlẹ ninu ọkan rẹ. Imọlẹ kan mọ loju rẹ, Ẹrin si bọ ni ẹnu rẹ, O n f'ede t'ahọn wa ko mọ, Sọrọ ogo t'o sunmọle. Itansan 'mọlẹ t'ọrun wa, Lati gba niyanju lọna; Awọn angel duro yika, Lati gbe lọ s'ibugbe wọn. Oluwa, jẹ k'a lọ bayi, K'a ba Ọ yọ, k'a r'oju Rẹ, Tẹ aworan Rẹ s'ọkan wa, Si kọ wa b'a ti ba Ọ rin. AMIN

Hymn 758 – IGBA asale ti dun to | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia