Hymn 757 – A! won ti gun s'ebute | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "A! won ti gun s'ebute" (C&S Hymn #757, Yoruba). A! wọn ti gun s'ebute, Loke ọrun; Loke ọrun; Ebi ko ni pa wọn mọ, Wọn…
A! wọn ti gun s'ebute, Loke ọrun; Loke ọrun; Ebi ko ni pa wọn mọ, Wọn bọ lọwọ irora, Loke ọrun; Loke ọrun. A! wọn ko wa fitila, Loke ọrun; Loke ọrun. 'Mọle ni l'ọjọ gbogbo, Jesu si n'Imọlẹ wọn, Loke ọrun; Loke ọrun. A! wura n'ita wọn jẹ, Loke ọrun; Loke ọrun. Ogo 'bẹ si pọ pupọ, Agbo Jesu ni wọn jẹ, Loke ọrun; Loke ọrun. A! otutu ki mu wọn, Loke ọrun; Loke ọrun. Owo rẹ wọn ti kọja, Gbogbo ọjọ l'o dara; Loke ọrun; Loke ọrun. A! wọn dẹkun ija 'ja, Loke ọrun; Loke ọrun. Jesu l'o ti gba wọn la, T'awọn Tirẹ l'o si n rin, Loke ọrun; Loke ọrun. A! wọn ko ni sọkun mọ, Loke ọrun; Loke ọrun. Jesu sa wa lọdọ wọn, Lọdọ Rẹ ni ayọ wa, Loke ọrun; Loke ọrun. A! a o dapọ mọ wọn, Loke ọrun; Loke ọrun. A n reti akoko wa, 'Gba Oluwa ba pe ni, S'oke ọrun, S'oke ọrun. AMIN
Hymn 757 – A! won ti gun s'ebute | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia