Hymn 756 – 'GBA ta kun fun 'banuje | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "'GBA ta kun fun 'banuje" (C&S Hymn #756, Yoruba). 'GBA ta kun fun 'banujẹ, Gb'omije n san loju wa; Gba t'a n sọkun t'a…

Hymn 756 – 'GBA ta kun fun 'banuje | C&S Yoruba Hymnary
'GBA ta kun fun 'banujẹ, Gb'omije n san loju wa; Gba t'a n sọkun t'a n sọfọ, Olugbala, gbọ tiwa. 'Wọ ti gbe ara wa wọ, O si mọ 'banujẹ wa; O ti sọkun bi awa, Olugbala, gbọ tiwa. 'Wọ ti tẹriba fun 'ku, 'Wọ ti t'ẹjẹ Rẹ silẹ; A tẹ Ọ si posi ri, Olugbala, gbọ tiwa. Gba t'ọkan wa ba bajẹ, Nitori ẹsẹ t'a da; Gba t'ẹru ba b'ọkan wa, Olugbala, gbọ tiwa. 'Wọ ti mọ ẹru ẹsẹ, Ẹsẹ ti ki se Tirẹ; Ẹru ẹsẹ na l'O gbe, Olugbala, gbọ tiwa. O ti silẹkun iku, O ti s'etutu f'ẹsẹ, O wa lọw' ọtun Baba, Olugbala, gbọ tiwa. AMIN

Hymn 756 – 'GBA ta kun fun 'banuje | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia