Hymn 754 – ALABUKUN l'awon oku | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "ALABUKUN l'awon oku" (C&S Hymn #754, Yoruba). ALABUKUN l'awọn oku Nipa ti Oluwa, Kowe rẹ bẹni Ẹmi wi, 'Sẹ wọn n tọ wọn…
ALABUKUN l'awọn oku Nipa ti Oluwa, Kowe rẹ bẹni Ẹmi wi, 'Sẹ wọn n tọ wọn lẹhin. Wọn sinmi ninu lala wọn, Kuro l'aginju yi, Wọn n yọ larin Ẹgbẹ Mimọ, Loke ọrun lọhun. Ayọ wọn ko se f'ẹnu sọ, Larin Ẹgbẹ Ogo, Jesu ti wọn ti gbẹkẹle, Si ti rẹ wọn lẹkun. Ainiye l'awọn Kérúbù, To y'itẹ Baba ka; Seraf' t'ẹnikan ko le ka, Wọn n kọ Halleluyah! Agbagba Mẹrinlelogun, Ẹda 'alaye Mẹrin, Wọn y'itẹ Olugbala ka, Wọn n kọ Mimọ, Mimọ. Ẹwa ogo 'bẹ ti pọ to? A ko le fẹnu sọ; Didan l'awọn ta se logo, Wọn n kọ orin Mose. A f'ogo fun Baba l'oke, A f'ogo fun Ọmọ, A f'ogo fun Ẹmi Mimọ , Mẹtalọkan lailai. AMIN
Hymn 754 – ALABUKUN l'awon oku | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia