Hymn 753 – AWON t'o sowon fun wa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "AWON t'o sowon fun wa" (C&S Hymn #753, Yoruba). AWỌN t'o sọwọn fun wa, Ninu Ẹgbẹ Séráfù, Wọn ti lọ s'ayérayé, Ko ha yẹ…
AWỌN t'o sọwọn fun wa, Ninu Ẹgbẹ Séráfù, Wọn ti lọ s'ayérayé, Ko ha yẹ k'a ranti wọn? Awọn t'o sọwọn fun wa, Larin Ẹgbẹ Kérúbù, Wọn dapọ mọ'jọ t'ọrun, Isẹ wọn n tọ wọn lẹhin. Awọn t'o sọwọn fun wa, Ninu Ẹgbẹ Aladura; Ẹni t'o ku ti pari, Isẹ rẹ l'ọdọ Jesu Awọn wọnyi ti sẹgun, F'ọla Olugbala wọn, Wọn ti gb'ohun Jesu pe, Bọ s'ayọ Oluwa Rẹ. Oluwa gbadura wa, K'a le ni'po lọdọ Rẹ, K'a ma tan bi irawọ, Titi lai lọd' Oluwa. mp Ẹ f'ogo fun Baba wa, Ẹ f'ogo fun Ọmọ Rẹ, Ẹ f'ogo f'Ẹmi Mimọ, Ogo fun Mẹtalọkan. AMIN
Hymn 753 – AWON t'o sowon fun wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia