Hymn 752 – ADORIN odun ni ye odun wa | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "ADORIN odun ni ye odun wa" (C&S Hymn #752, Yoruba). ADỌRIN ọdun ni ye ọdun wa, Bi ọjọ alagbase; A o ke wa lulẹ bi…

Hymn 752 – ADORIN odun ni ye odun wa | C&S Yoruba Hymnary
ADỌRIN ọdun ni ye ọdun wa, Bi ọjọ alagbase; A o ke wa lulẹ bi itanna eweko, Awa a si kọja lọ. O digbose (arakunrin tabi arabinrin) O digbose, (Arakunrin tabi arabinrin) O d'ọjọ ajinde. Koriko, b'o ku ko tun le ye mọ Iwọ ku lati tun ye; Ade ti ki sa yoo jẹ tirẹ, Lọdọ Olugbala. O digbose (arakunrin tabi arabinrin) O digbose, (Arakunrin tabi arabinrin) O d'ọjọ ajinde. Losu to kọja; t'awa tirẹ ni, Loni ipo rẹ s'ofo; (Arakunrin, Arabinrin) wa ko lọ s'idalẹ. Iku lo ti mu lọ. O digbose (arakunrin tabi arabinrin) O digbose, (Arakunrin tabi arabinrin) O d'ọjọ ajinde. Jẹ ki eyi jẹ ẹkọ fun gbogbo wa, Lati tun wa wa se; Igi gbigbẹ le wa ni iduro, K'a ke tutu lulẹ O digbose (arakunrin tabi arabinrin) O digbose, (Arakunrin tabi arabinrin) O d'ọjọ ajinde. Iwa wa layé yoo jẹri si wa, Bi 'gbẹyin y'o ti ri; Rere (Arakunrin, Arabinrin) ti n tọ lẹhin; O ti se wọn to le se O digbose (arakunrin tabi arabinrin) O digbose, (Arakunrin tabi arabinrin) O d'ọjọ ajinde. Ẹgbẹ, at'Ẹbi (Arakunrin, Arabinrin) wa, A ba yin daro lọkan; Ireti mbẹ a o pade loke, Ni ọjọ Ajinde wa. O digbose (arakunrin tabi arabinrin) O digbose, (Arakunrin tabi arabinrin) O d'ọjọ ajinde. AMIN O digbose (arakunrin tabi arabinrin) O digbose, (Arakunrin tabi arabinrin) O d'ọjọ ajinde.

Hymn 752 – ADORIN odun ni ye odun wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia