Hymn 734 – EGBE Serafu, e dide | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "EGBE Serafu, e dide" (C&S Hymn #734, Yoruba). Ẹgbẹ Séráfù, ẹ dide, Ẹ d'amure yin giri; Ọlọrun lo d'ẹgbẹ yi silẹ, Ẹ ma…
Ẹgbẹ Séráfù, ẹ dide, Ẹ d'amure yin giri; Ọlọrun lo d'ẹgbẹ yi silẹ, Ẹ ma jẹ k'ẹru ba yin Lọ wasu ihinrere Rẹ, Yio pẹlu wa titi d'opin, Kẹ 'sa ma wo Jesu ni ọkan, Titi a o fi sẹgun. Ẹgbẹ Séráfù, ẹ dide, Lati tan Ọrọ Ọlọrun; Paapaa larin ilu Eko, F'awọn to ti sako lọ, Ka le r'ẹni irapada, Larin awọn ti o n segbe lọ, Lati ran wọn s'agbo Jesu, Si iye ainipẹkun. AMIN
Hymn 734 – EGBE Serafu, e dide | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia