Hymn 733 – EGBE Kerubu Serafu | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "EGBE Kerubu Serafu" (C&S Hymn #733, Yoruba). ẸGBẸ Kérúbù Seraf' Ẹgbẹ ogun ọrun, Ẹgbẹ awọn Apostel, Ẹgbẹ Ijọ Mimọ,…

Hymn 733 – EGBE Kerubu Serafu | C&S Yoruba Hymnary
ẸGBẸ Kérúbù Seraf' Ẹgbẹ ogun ọrun, Ẹgbẹ awọn Apostel, Ẹgbẹ Ijọ Mimọ, Gbogbo wọn loke ọrun, N yin Ọ t'ọsan, t'oru, W'Ọlọrun Mẹtalọkan; Ọga Ogo julọ. Awa Ẹgbẹ Séráfù, Ayé yin Ọ, Baba, Ifẹ Tirẹ ni ki a se, Bi wọn ti n se lọrun; Pẹlu wa b'a ti pejọ, Jẹ k'a le sin l'emi, Baba wa, jọ sọkalẹ, F'ogo Rẹ han nihin. Larin ainiye ibi, To rọgba yi wa ka, Larin 'jamba oun 'pọnju, To ja ni igboro wa; Emi o f'ọpẹ fun Ọ, Tori Iwọ da mi si: Ọba Afẹnifẹ-re, Ogo f'Orukọ Rẹ. 'Gba Noah rubọ ọpẹ, 'Wọ f'osumare han; Majẹmu pe ikunmi, Ki yoo bo ayé mọ; Baba f'osumare han, N'irubọ isin wa, K'a mase ri ibi mọ, Jekejado 'le wa. 'Wọ lo d'Ẹgbẹ yi silẹ, Se Ẹgbẹ na logo; S'Amọna at'Odi rẹ, Larin 'danwo ayé; Baba Olodumare; 'Wọ lo n pe ko yẹni; Jẹ k'o y'Ẹgbẹ yi kalẹ, Nitori Ọmọ Rẹ. AMIN

Hymn 733 – EGBE Kerubu Serafu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia