Hymn 732 – BABA Aladura mura | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "BABA Aladura mura" (C&S Hymn #732, Yoruba). BABA Aladura mura, Lati pade Kérúbù, Jesu lo pe ọ, lo yan ọ Lati d'Ẹgbẹ yi…
BABA Aladura mura, Lati pade Kérúbù, Jesu lo pe ọ, lo yan ọ Lati d'Ẹgbẹ yi silẹ, O si pe gbogbo ayé la ti wọ 'kọ 'gbala yi, B'ọjọ wa ti n kọja lọ. Ojọ n lọ, ọjọ n lọ (2ce) Ise pọ t'awa o se, B'ọjọ wa ti n kọja lọ. Ẹgbẹ Aladura mura, Lati pade Kérúbù: Ẹ ma jẹ k'amure yin tu, Lati pade Kérúbù; Gbe Ida 'sẹgun s'oke, Iye s'Ọlọrun Daniel, Aleluya! Jesu mbọ, B'ọjọ wa ti n kọja lọ. Ojọ n lọ, ọjọ n lọ (2ce) Ise pọ t'awa o se, B'ọjọ wa ti n kọja lọ. Ọlọrun Mẹtalọkan wa, Lati gbọ adura wa , Jesu Olugbala Ọba, Jọwọ gb'ẹbọ ọpẹ wa, Ẹmi Mimọ sokalẹ, F'ore-ọfẹ ba wa gbe, Isẹ pọ t'awa o se, B'ọjọ wa ti n kọja lọ. Ojọ n lọ, ọjọ n lọ (2ce) Ise pọ t'awa o se, B'ọjọ wa ti n kọja lọ. Okun ‘fẹ so gbogbo wa pọ, B'ọjọ wa ti n kọja lọ; Kankan la o fa wọn s'agbo Rẹ, B'ọjọ wa ti n kọja lọ, Sugbọn eso ọrọ Rẹ, N dagba l'ọsan at'oru, Gb'awọn to subu dide, B'ọjọ wa ti n kọja lọ. Ọjọ n lọ, Ọjọ n lọ (2ce) Isẹ pọ t'awa o se, B'ọjọ wa ti n kọja lọ. AMIN Ọjọ n lọ, Ọjọ n lọ (2ce) Isẹ pọ t'awa o se, B'ọjọ wa ti n kọja lọ.
Hymn 732 – BABA Aladura mura | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia