Hymn 735 – EYIN omo Egbe Serafu | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "EYIN omo Egbe Serafu" (C&S Hymn #735, Yoruba). ẸYIN ọmọ Ẹgbẹ Séráfù, Ẹ ko le p'e ẹ o ko'ya, Ẹyin ọmọ Ẹgbẹ Kérúbù, Ẹ ko…

Hymn 735 – EYIN omo Egbe Serafu | C&S Yoruba Hymnary
ẸYIN ọmọ Ẹgbẹ Séráfù, Ẹ ko le p'e ẹ o ko'ya, Ẹyin ọmọ Ẹgbẹ Kérúbù, Ẹ ko le pe ẹ o ko'ya. Ẹyin ọm'ogun 'gbala yi, Ẹ ko le pe ẹ o k'ẹgan, Ẹ ko le kọ 'nunibini, Ati keta gbogbo. Ẹ gb'ohun Olugbala wa, B'o ti n wi jẹjẹ pe; Ranti mi lor'agbelebu, At'ọwọ at'ẹsẹ. Bi a ba foriti 'pọnju, Ti a si ru 'tiju, Ade ogo 'rawọ Owurọ, Y'o jẹ tiwa n'kẹhin. A o pẹlu awọn t'ọrun Lati ma juba Rẹ; A o si ma kọ orin Mose, Ati t'Ọdaguntan. Orin Halle, Haleluya! Iyin si Ọba wa, Mẹtalọkan Ayérayé, Baba, Ọmọ, Ẹmi. AMIN

Hymn 735 – EYIN omo Egbe Serafu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia