Hymn 073 – MIMO, Mimo, Mimo Olodumare | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "MIMO, Mimo, Mimo Olodumare" (C&S Hymn #073, Yoruba). APA KINI 1. MIMỌ, Mimọ, Mimọ Olodumare, Ni kutukutu ni'wọ o gbọ…

Hymn 073 – MIMO, Mimo, Mimo Olodumare | C&S Yoruba Hymnary
APA KINI 1. MIMỌ, Mimọ, Mimọ Olodumare, Ni kutukutu ni'wọ o gbọ orin wa, Mimọ, Mimọ, Mimọ! Oniyọnu julọ, Ologo mẹta lai Olubukun. 2. Mimọ, Mimọ, Mimọ, awọn t'ọrun n yin, Wọn n fi ade wura wọn lelẹ y'itẹ ka, Kerubim Serafim n wolẹ niwaju Rẹ. Wọ to ti wa to si wa titi lai. 3. Mimọ, Mimọ, Mimọ, B'okunkun pa ọ mọ, Bi oju ẹlẹsẹ ko le ri ogo Rẹ, Iwọ nikan lo mọ, ko tun si ẹlomi, Pipe 'nu agbara ati n'ifẹ. 4. Mimọ, Mimọ, Mimọ, Olodumare, Gbogbo isẹ Rẹ n'ilẹ l'oke lo n yin Ọ, Mimọ, Mimọ, Mimọ, Oniyọnu julọ, Ologo mẹta lai Olubukun. AMIN APA KEJI 1. MIMỌ, Mimọ, Mimọ, Olodumare, Baba, Ọmọ, Ẹmi Ẹlẹda Olootọ, Mimọ, Mimọ, Mimọ, Olododo julọ, Pipe 'nu iwa lai Olubukun. 2. Mimọ, Mimọ, Mimọ, gbogbo ayé gberin, Kọrin 'yin k'ayé Ẹni Mẹtalọkan, Ọlọrun alagbara Ọlọrun Olufẹ, Olupamọ Olore ọfẹ. 3. Mimọ, Mimọ, Mimọ, yọ ẹni 'rapada, Da ohun yin pọ mọ t'awọn ti n yin l'ọrun, Titi lai ni k'ẹ yin Mimọ, Mimọ, Mimọ, F'ẹni Mẹtalọkan ayérayé. 4. Mimọ, Mimọ, Mimọ, Olodumare, Ogo, Ọla, Ọgbọn, Agbara ni Tirẹ, Mimọ, fun Ẹmi Mimọ ti o gunwa, Ẹlẹru ni iyin Ẹni 'yanu. AMIN

Hymn 073 – MIMO, Mimo, Mimo Olodumare | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia