Hymn 074 – BABA niwaju ite Re | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "BABA niwaju ite Re" (C&S Hymn #074, Yoruba). 1. BABA niwaju itẹ Rẹ, L'Angẹli n tẹriba, Nigba gbogbo niwaju Rẹ, Ni wọn…
1. BABA niwaju itẹ Rẹ, L'Angẹli n tẹriba, Nigba gbogbo niwaju Rẹ, Ni wọn n kọrin iyin, Wọn si n fi ade wura wọn, Lelẹ y'itẹ naa ka, Wọn n fi ohun pẹlu duru, Kọrin si Oluwa. 2. Didan osumare si n tan Si ara iyẹ wọn, Bi Seraf' ti n ke si Seraf', Ti wọn kọrin 'yin Rẹ, Bi a ti kunlẹ nihin yii, Ran ore Rẹ si wa, Ka mọ pe 'Wọ wa nitosi, Lati da wa l'ohun. 3. Nihin nibi t'awọn Angẹli, N wo wa, ba ti n sin Ọ, Kọ wa k'a wa ile ọrun, K'a sin Ọ bi ti wọn, K'a ba wọn kọ orin iyin, K'a ba wọn mọ 'fẹ Rẹ, Titi agbara y'o fi di, Tirẹ Tirẹ nikan. AMIN
Hymn 074 – BABA niwaju ite Re | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia