Hymn 072 – OBA awon eni mimo | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OBA awon eni mimo" (C&S Hymn #072, Yoruba). 1. ỌBA awọn ẹni mimọ T'o mọ 'ye awọn 'rawọ; Ọpọ ẹni t'Ẹda gbagbe, Wa yika…
1. ỌBA awọn ẹni mimọ T'o mọ 'ye awọn 'rawọ; Ọpọ ẹni t'Ẹda gbagbe, Wa yika itẹ Rẹ lai. Mimọ Mimọ (6 times) Lo ye Ọ, Iwọ l'a ba ma f'iyin fun, Ọlọrun, Edumare. 2. Ẹni t'o wa ninu 'mọlẹ, T'oju ẹnikan ko ri; Mose ri akẹyinsi Rẹ, Oju Mose ran b'orun. 3. 'Mọlẹ ti 'kuku ayé bo, N tan 'mọlẹ roro loke; Wọn jẹ ọmọ alade l'ọrun, Ẹda gbagbe wọn l'ayé. 4. mf Lala at'iya wọn fun Ọ, Ẹda ko royin rẹ mọ; Iwa rere wọn farasin, Oluwa nikan lo mọ. 5. p Wọn farasin fun wa sugbọn, A kọ wọn s'iwe iye, Igbagbọ, adura, suuru, Lala oun 'jakadi wọn. 6. Wọn mọ isura Rẹ lọhun, Ka wa mọ wọn Oluwa; Nigba t'O ba n siro ọsọ, Ti mbẹ lara ade Rẹ. 7. Ẹ wolẹ f'Ọba Ologo, Séráfù ẹ wolẹ fun Niwaju itẹ Jehovah, Ọlọrun Mẹtalọkan. 8. mp Ẹ wolẹ f'Ọba Ologo, Kérúbù ẹ wolẹ fun; Niwaju itẹ Jehovah, Ọlọrun Mẹtalọkan AMIN
Hymn 072 – OBA awon eni mimo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia