Hymn 71 – GBANGBA l'oju Re Olorun | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "GBANGBA l'oju Re Olorun" (C&S Hymn #71, Yoruba). 1. GBANGBA l'oju Rẹ Ọlọrun, Sohun gbogbo ta n se; T'ọsan t'oru bakan…

Hymn 71 – GBANGBA l'oju Re Olorun | C&S Yoruba Hymnary
1. GBANGBA l'oju Rẹ Ọlọrun, Sohun gbogbo ta n se; T'ọsan t'oru bakan naa ni, Loju Oluwa wa. 2. Ko s'ẹsẹ kan ti a le da, Ko s'ọrọ t'a le sọ; Ti ko si ninu iwe Rẹ, Fun iranti gbogbo. 3. Ẹsẹ ole, ẹsẹ irọ, Ẹsẹ aiforiji; Ẹsẹ ka sọrọ ẹni lẹhin, Baba dariji wa. 4. Ẹsẹ igberaga ọkan, Ẹsẹ isọkusọ; Ẹsẹ aini 'gbagbọ daju, Baba dariji wa. 5. A! l'ọjọ nla ọjọ 'dajọ, Ma jẹ k'oju tiwa; T'oju gbogbo ayé yoo pe, Baba dariji wa. 6. Dariji mi Ọlọrun mi, Ki n to lọ layé yi; Si pa gbogbo ẹsẹ mi rẹ, Baba dariji mi. AMIN

Hymn 71 – GBANGBA l'oju Re Olorun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia