Hymn 721 – OJO nla l'eyi je | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OJO nla l'eyi je" (C&S Hymn #721, Yoruba). ỌJỌ nla l'eyi jẹ, T'a n se Ajọdun wa, Kérúbù, ẹ ho ye, Séráfù, ẹ gberin,…

Hymn 721 – OJO nla l'eyi je | C&S Yoruba Hymnary
ỌJỌ nla l'eyi jẹ, T'a n se Ajọdun wa, Kérúbù, ẹ ho ye, Séráfù, ẹ gberin, Halleluyah, Halleluyah, S'Ọba wa, Ẹni ti o da wa si, Lati tun ri ọdun yi, Ogo f'orukọ Rẹ. Orun pẹl' Osupa, Ẹ fi ayọ yin han, F'ẹmi wa to d'oni, Larin Ẹgbẹ Kérúbù. Halleluyah, Halleluyah, S'Ọba wa, Ẹni ti o da wa si, Lati tun ri ọdun yi, Ogo f'orukọ Rẹ. Sure fun wa loni, Baba Mimọ t'ọrun, Ma jẹ ki a rahun, Nikẹhin ayé wa, Halleluyah, Halleluyah, S'Ọba wa, Ẹni ti o da wa si, Lati tun ri ọdun yi, Ogo f'orukọ Rẹ. Iru Ẹgbẹ Seraf' Larin Ilu Afrika, Igba wa sunmọle, T'a o bọ l'oko ẹru, Halleluyah, Halleluyah, S'Ọba wa, Ẹni ti o da wa si, Lati tun ri ọdun yi, Ogo f'orukọ Rẹ. A dupẹ, Oluwa, Fun Ajọdun oni, T'o s'oju ẹmi wa, Lori 'lẹ alaye Halleluyah, Halleluyah, S'Ọba wa, Ẹni ti o da wa si, Lati tun ri ọdun yi, Ogo f'orukọ Rẹ. Ajọdun nla kan mbẹ, T'a o se loke Ọrun, Pẹlu awọn Mimọ, Fun iyin Oluwa, Halleluyah, Halleluyah, S'Ọba wa, Ẹni ti o da wa si, Lati tun ri ọdun yi, Ogo f'orukọ Rẹ. A dupẹ, Oluwa, Pe O ti gbọ tiwa, Ma jẹ k'a d'ẹsẹ mọ, K'a l'ayọ nikẹhin. Halleluyah, Halleluyah, S'Ọba wa, Ẹni ti o da wa si, Lati tun ri ọdun yi, Ogo f'orukọ Rẹ. AMIN Halleluyah, Halleluyah, S'Ọba wa, Ẹni ti o da wa si, Lati tun ri ọdun yi, Ogo f'orukọ Rẹ.

Hymn 721 – OJO nla l'eyi je | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia