Hymn 722 – OLORUN Olodumare | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OLORUN Olodumare" (C&S Hymn #722, Yoruba). ỌLỌRUN Olodumare, A dupẹ fun 'dasi oni, Ajọdun yi si tun ba wa, Ni ori ilẹ…
ỌLỌRUN Olodumare, A dupẹ fun 'dasi oni, Ajọdun yi si tun ba wa, Ni ori ilẹ agbayé, A s'ọpẹ, a s'ọpẹ, Fun idasi wa l'ọdun yi, Larin ọta, larin ẹgan, Larin awọn oninubini, A s'ọpẹ, a s'ọpẹ, Fun idasi wa l'ọdun yi. Ajọdun oni ko ba wa, Ha! ayọ t'ọrun ko l'opin, Ẹgbẹ t'o t'ọrun sọkalẹ, Iru eyi ko si layé. A s'ọpẹ, a s'ọpẹ, Fun idasi wa l'ọdun yi, Larin ọta, larin ẹgan, Larin awọn oninubini, A s'ọpẹ, a s'ọpẹ, Fun idasi wa l'ọdun yi. Ọkunrin ati Obinrin, Ẹ mura k'ẹ d'amure yin, Ọmọde at'agbalagba, Ki gbogbo wa kọrin s'oke, A s'ọpẹ, a s'ọpẹ, Fun idasi wa l'ọdun yi, Larin ọta, larin ẹgan, Larin awọn oninubini, A s'ọpẹ, a s'ọpẹ, Fun idasi wa l'ọdun yi. Ajẹ, Oso, Alawirin, Sanpọnna, ologun ika, Igunnu at'awọn elegun, Ko n'ipa kan lor'Ẹgbẹ na. A s'ọpẹ, a s'ọpẹ, Fun idasi wa l'ọdun yi, Larin ọta, larin ẹgan, Larin awọn oninubini, A s'ọpẹ, a s'ọpẹ, Fun idasi wa l'ọdun yi. Nigba t'Ẹgbẹ yi ko bere, Awọn kan n reti eleya, Wọn sebi ẹgbẹ lasan ni, Wọn ko mọ isẹ Ọlọrun. A s'ọpẹ, a s'ọpẹ, Fun idasi wa l'ọdun yi, Larin ọta, larin ẹgan, Larin awọn oninubini, A s'ọpẹ, a s'ọpẹ, Fun idasi wa l'ọdun yi. Mẹtalọkan l'Ọlọrun wa, Ọlọrun ti ko n'ipẹkun, Baba, Ọmọ, Ẹmi Mimọ , Gbogbo wọn lo n sisẹ wọn pọ. A s'ọpẹ, a s'ọpẹ, Fun idasi wa l'ọdun yi, Larin ọta, larin ẹgan, Larin awọn oninubini, A s'ọpẹ, a s'ọpẹ, Fun idasi wa l'ọdun yi. AMIN A s'ọpẹ, a s'ọpẹ, Fun idasi wa l'ọdun yi, Larin ọta, larin ẹgan, Larin awọn oninubini, A s'ọpẹ, a s'ọpẹ, Fun idasi wa l'ọdun yi.
Hymn 722 – OLORUN Olodumare | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia