Hymn 720 – OJO ayo l'eyi je | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OJO ayo l'eyi je" (C&S Hymn #720, Yoruba). ỌJỌ ayọ l'eyi jẹ, Awa n s'ajọdun wa; Kérúbù n pe Séráfù, Ẹ jade wa woran.…

Hymn 720 – OJO ayo l'eyi je | C&S Yoruba Hymnary
ỌJỌ ayọ l'eyi jẹ, Awa n s'ajọdun wa; Kérúbù n pe Séráfù, Ẹ jade wa woran. Halleluyah! Kọrin kikan soke, Halleluyah! f'Ọba Ọlọrun wa. Ẹgbẹ ogun ọrun n ki wa, Pe mase jafara; Akoko diẹ lo ku, T'ayé y'o kọja lọ. Halleluyah! Kọrin kikan soke, Halleluyah! f'Ọba Ọlọrun wa. Ohun iyanu l'eyi, Nipa ti Ẹgbẹ na; Nigba t'igbagbọ ti sẹ, A ko ri iru eyi ri. Halleluyah! Kọrin kikan soke, Halleluyah! f'Ọba Ọlọrun wa. Gbogb' awọn alailera, T'o wa nin' Ẹgbẹ na; Ọkunrin at'Obrinrin, N jẹri si eyi na, Halleluyah! Kọrin kikan soke, Halleluyah! f'Ọba Ọlọrun wa. 'Wọn to wa nigberiko, N jẹri si otitọ; Pe ajẹ ko n'ipa mọ, 'Nu ẹgbẹ Séráfù. Halleluyah! Kọrin kikan soke, Halleluyah! f'Ọba Ọlọrun wa. Awọn t'o wa n'idalẹ, Wọn n sọpẹ, wọn si n jo, Sanpọnna ko n'ipa mọ, 'Nu ẹgbẹ Kérúbù Halleluyah! Kọrin kikan soke, Halleluyah! f'Ọba Ọlọrun wa. Séráfù ma gbode kan, Ko si'ru eyi ri; Kérúbù ma gbode kan, Wọn n ji oku dide. Halleluyah! Kọrin kikan soke, Halleluyah! f'Ọba Ọlọrun wa. Ogo fun Baba l'oke, Ogo ni fun Ọmọ; Ogo ni fun Ẹmi Mimọ , Mẹtalọkan lailai. Halleluyah! Kọrin kikan soke, Halleluyah! f'Ọba Ọlọrun wa. AMIN Halleluyah! Kọrin kikan soke, Halleluyah! f'Ọba Ọlọrun wa.

Hymn 720 – OJO ayo l'eyi je | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia