Hymn 719 – Ki l'o tun yẹ wa loni yi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Ki l'o tun yẹ wa loni yi" (C&S Hymn #719, Yoruba). Ki l'o tun yẹ wa loni yi, Bi k'a jo k'a yọ s'Oluwa, T'o mu wa…
Ki l'o tun yẹ wa loni yi, Bi k'a jo k'a yọ s'Oluwa, T'o mu wa r'ọdun yi l'ayọ, Ẹ ho, ẹ ke Halleluyah. Eyi daju ni tiwa pe, Jesu Kristi wa larin wa; O ni k'a f'ọkan wa balẹ, Baba ko ni jẹ k'a yanku. B'Oluwa ko kọ ile na, Awọn ti n kọ n sisẹ lasan, B'Oluwa ko pa ilu mọ, Olusọ sa kan ji lasan. Gbogbo Ẹyin asiwaju, Tẹsiwaju n'isẹ Oluwa, Baba y'o f'agbara wọ yin, Lati sẹgun esu at'ẹsẹ. Oluwa y'o dabo bo wa, Ọlọmọ ko ni padanu, Agan y'o tọwọ rẹ b'osun Aboyun y'o bi l'abiye. AMIN
Hymn 719 – Ki l'o tun yẹ wa loni yi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia