Hymn 711 – E ku ewu odun, E ku 'yedun | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "E ku ewu odun, E ku 'yedun" (C&S Hymn #711, Yoruba). Ẹ ku ewu ọdun, Ẹ ku 'yedun A s'ọpẹ fun Ọlọrun wa, T'o mu wa ri…

Hymn 711 – E ku ewu odun, E ku 'yedun | C&S Yoruba Hymnary
Ẹ ku ewu ọdun, Ẹ ku 'yedun A s'ọpẹ fun Ọlọrun wa, T'o mu wa ri ajọdun oni yi, Ni ori ilẹ ayé. Awa dupẹ, a tun ọpẹ da, Ogo, Ọla, at'Agbara ati 'pa, F'Ọd'aguntan t'o gunwa. Kristi se 'mọlẹ at'alabo wa, M'ẹsẹ agbo Rẹ yi duro; Pese isẹ f'awọn ti ko ri se, Se 'wosan alaisan. Awa dupẹ, a tun ọpẹ da, Ogo, Ọla, at'Agbara ati 'pa, F'Ọd'aguntan t'o gunwa. Oluwa ni Olus'Àgùntàn mi, Emi ki yoo se alaini, O mu mi dubulẹ ni papa oko tutu, O tu ọkan mi l'ara. Awa dupẹ, a tun ọpẹ da, Ogo, Ọla, at'Agbara ati 'pa, F'Ọd'aguntan t'o gunwa. Bi emi ba tilẹ n rin kọja lọ, Larin afonifoji 'ku Emi ki o si bẹru ibi kan, 'Tori 'Wọ wa pẹlu mi. Awa dupẹ, a tun ọpẹ da, Ogo, Ọla, at'Agbara ati 'pa, F'Ọd'aguntan t'o gunwa. Awọn ọgọ Rẹ ati ọpa Rẹ, Awọn ni o tu mi ninu; O tẹ tabil' Ounjẹ silẹ n'iwaju, L'oju awọn ọta mi. Awa dupẹ, a tun ọpẹ da, Ogo, Ọla, at'Agbara ati 'pa, F'Ọd'aguntan t'o gunwa. Iwọ da ororo si mi l'ori, Ago mi k'akun wọ silẹ, Ire, anu ni yoo ma tọ mi lẹhin, L'ọjọ ayé mi gbogbo. Awa dupẹ, a tun ọpẹ da, Ogo, Ọla, at'Agbara ati 'pa, F'Ọd'aguntan t'o gunwa. Kristi Olugbala awa mbẹ Ọ, Jọwọ ran Ẹmi Rẹ si wa, K'a le wọ wa l'asọ Ogo didan, Ni ikẹhin ọjọ ayé wa. Awa dupẹ, a tun ọpẹ da, Ogo, Ọla, at'Agbara ati 'pa, F'Ọd'aguntan t'o gunwa. Kabiyesi, Ọba Alayéluwa, Mẹtalọkan Ayérayé, Fun wa n'isẹgun n'igba idanwo, K'ọwọ esu ma tẹ wa. Awa dupẹ, a tun ọpẹ da, Ogo, Ọla, at'Agbara ati 'pa, F'Ọd'aguntan t'o gunwa. Baba oke ọrun awa mbẹ Ọ, Sure fun wa k'a wa to lọ, Jesu bẹbẹ fun awa ọmọ Rẹ, K'a le j'Ọba pẹlu Rẹ. Awa dupẹ, a tun ọpẹ da, Ogo, Ọla, at'Agbara ati 'pa, F'Ọd'aguntan t'o gunwa. AMIN Awa dupẹ, a tun ọpẹ da, Ogo, Ọla, at'Agbara ati 'pa, F'Ọd'aguntan t'o gunwa.

Hymn 711 – E ku ewu odun, E ku 'yedun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia