Hymn 710 – EGBE Serafu t'Kerubu ti Oke Sioni | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "EGBE Serafu t'Kerubu ti Oke Sioni" (C&S Hymn #710, Yoruba). Full: ẸGBẸ Séráfù t'Kérúbù ti Oke Sioni, A! a ku idaraya…
Full: ẸGBẸ Séráfù t'Kérúbù ti Oke Sioni, A! a ku idaraya ọdun o, A pegede ) 2ce Ebenezer lo n sin wa, Ẹgbẹ Séráfù, a o rire o, Ajọdun miran la mi se o, ọpẹ o Edumare, Ọgba ajara ta mi tọju, Ko kun f'oyin ati wara, A ku idaraya ọdun o, a pegede, Ebenezer lo n sin wa, Ẹgbẹ Séráfù a o rire o A ki Ọ Alagba wa oni, ẹmi rẹ a ma gun, Ile rẹ ko ni gbona; Ijọngbọn o ni wọ 'le rẹ; Amọdi o ni wọ 'le rẹ, Ọmọ Arayé ko ni ri ẹ gbe se, o lagbara Edumare A ku idaraya ọdun o, a pegede, Ebenezer lo n sin wa, Ẹgbẹ Kérúbù a o rire o Solo: Ẹyin ọrẹ tẹ gbọ dide wa, Ọba k'O ran yin lọwọ. Ibukun ko ni gbe n'ile yin o bi iyanrin okun ni. Solo: T'ọmọde t'agba tẹ gbẹ dide wa, Ọba ko ran yin lọwọ. (Ibukun) L'ọkunrin, l'obinrin o, a dupẹ pupọ, ẹ ku abase, L'ọkunrin, l'obinrin Asiwaju n'nu jọ o; L'adehinbọ Ajọdun wa o, gbogbo yin l'ẹ o rire (Ibukun) A ku idaraya ọdun o a pegede, Ebenezer lo n sin wa, Ẹgbẹ Séráfù a o rire. Ibukun ko ni gbe n'ile yin o bi iyanrin okun ni. Solo: Baba Aladura, awa Aladura ojojumọ a ba ọ yọ, Fun aye ribiribi t'Edumare pe o si ninu Isẹ Baba. Full: Igun ki ku ni kekere, wa dagba kẹjẹ, ara rẹ a le ko ko ko, Ẹ ku idaraya ọdun o, pegede. Ebenezer lo mi si wa, Ẹgbẹ Kérúbù a o rire o. Swing Ibukun ko ni gbe n'ile yin o bi iyanrin okun ni. Solo: Ajọdun oni ki lo ti ri o (Oloyin ni) Ko ha yẹ ka ma jo 'ka ma yọ (rayin-rayin) Ibukun ko ni gbe n'ile yin o bi iyanrin okun ni. Full: A dupẹ pupọ Baba o se, to da wa si o, A o ma yin Ọ layé o titi lọ titi, Mo gboju soke mo wo rarara, oju pe, Lati oke titi lo dẹsẹ gbogbo wa jeniyan, A ro dẹdẹ, a gba dẹdẹ; a dupẹ pupọ Baba o, O se to da wa si o. A o ma yin Ọ layé o titi lọ titi, Ani ma jo ma yọ, ma jo ma jo Ka yọ sẹsẹ si Jah l'oke o karikari, Ka gbẹsẹ ọtun, ka gbe t'osi s'oke lalala, A o ma yin Ọ layé o titi, lọ titi. Ẹlu 'lu si mi lọrun gorogoro, Bata ni boya, dundun ni boya, botakoto ni boya, Sẹkẹrẹ ni 'boya, ka bo, s'ode ka yo se ara, ara bi o A o ma yin Ọ layé o titi lọ titi. Nile ayé dandan (Baba) 2ce Egbe Aladura ka rire O,…
Hymn 710 – EGBE Serafu t'Kerubu ti Oke Sioni | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia