Hymn 712 – EGBE Kerubu to jade | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "EGBE Kerubu to jade" (C&S Hymn #712, Yoruba). ẸGBẸ Kérúbù to jade, Awa lo n s'ajọdun wa, K'ogun ọrun ba wa gberin,…

Hymn 712 – EGBE Kerubu to jade | C&S Yoruba Hymnary
ẸGBẸ Kérúbù to jade, Awa lo n s'ajọdun wa, K'ogun ọrun ba wa gberin, K'arayé gbohun soke, Halleluya, Halleluya ) T'ewe t'agba ko gbe 'rin ) 2ce Ọpẹ lo yẹ f'Olugbala, Fun idasi wa oni; Ọta ka wa nibi gbogbo, Sugbọn Jesu ko wa yọ, Halleluya, Halleluya ) T'ewe t'agba ko gbe 'rin ) 2ce Ẹmi Mimọ ko pẹlu wa, L'ọkunrin at'lobinrin; Kérúbù pẹlu Séráfù, K'a pade n'ijọ t'ọrun, Halleluya, Halleluya ) T'ewe t'agba ko gbe 'rin ) 2ce Ọlọrun Olodumare, Ọbangiji Ọba wa; Ma jẹ k'ebi alẹ pa wa, K'ẹnikẹni ma pose. Halleluya, Halleluya ) T'ewe t'agba ko gbe 'rin ) 2ce Kérúbù pẹlu ogun rẹ, Ni awọn ariran n ri; Holy Maikeli pẹlu 'da Rẹ, O n gẹsin poyi wa ka. Halleluya, Halleluya ) T'ewe t'agba ko gbe 'rin ) 2ce Abo Oluwa Onikẹ, L'awa Ẹgbẹ bora mọ, Ko s'ohun ibi to le se wa , Lagbara Mẹtalọkan. Halleluya, Halleluya ) T'ewe t'agba ko gbe 'rin ) 2ce Ẹni l'oyun a bimọ la, Agan a f'ọwọ bosun; Olọmọ ko ni padanu, Iku ko ni ri wa gbe se. Halleluya, Halleluya ) T'ewe t'agba ko gbe 'rin ) 2ce Gbogbo awọn ti ko ri se, L'ọkunrin l'obinrin, Ipese Olodumare , Awamaridi lo jẹ. Halleluya, Halleluya ) T'ewe t'agba ko gbe 'rin ) 2ce Ẹ wa ba wa k'Alleluya, F'ọdun miran Kérúbù, T'Oluwa d'ẹgbẹ na silẹ, Larin Ẹgbẹ Séráfù. Halleluya, Halleluya ) T'ewe t'agba ko gbe 'rin ) 2ce Ọba aw'Ẹgbẹ Kérúbù, Jesu Kristi Oluwa, Awa n kọrin, awa si n yọ, Ogo fun Ọd'aguntan. Halleluya, Halleluya ) T'ewe t'agba ko gbe 'rin ) 2ce AMIN Halleluya, Halleluya ) T'ewe t'agba ko gbe 'rin ) 2ce

Hymn 712 – EGBE Kerubu to jade | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia