Hymn 707 – A KI yin e ku ajodun oni | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "A KI yin e ku ajodun oni" (C&S Hymn #707, Yoruba). A KI yin ẹ ku ajọdun oni, Ẹyin Ọmọ Ẹgbẹ Séráfù, A dupẹ lọwọ Baba wa…
A KI yin ẹ ku ajọdun oni, Ẹyin Ọmọ Ẹgbẹ Séráfù, A dupẹ lọwọ Baba wa ọrun, T'o da wa si di oni. Ẹ ho iho ayọ gbogbo Séráfù, Fun ogun rere ti a fun wa Lat' ọwọ Mose Orimolade, T'o d'Ẹgbẹ Séráfù s'ayé. Awọn olufẹ wa ti goke lọ, Wọn kọja s'aya Baba wa, Wọn n boju wo wa lati oke na, Lati wo b'a ti n sisẹ. Ẹ ho iho ayọ gbogbo Séráfù, Fun ogun rere ti a fun wa Lat' ọwọ Mose Orimolade, T'o d'Ẹgbẹ Séráfù s'ayé. Baba Aladura mura giri, Lati tẹle ọna na, Sisẹ pẹlu gbogbo agbara Rẹ, K'ẹgbẹ le tẹsiwaju. Ẹ ho iho ayọ gbogbo Séráfù, Fun ogun rere ti a fun wa Lat' ọwọ Mose Orimolade, T'o d'Ẹgbẹ Séráfù s'ayé. Ẹni Ọwọ'tun Baba Aladura, Ọgbẹni Senior Apostle Ati gbogbo awọn Apostle Ẹ gbe iwo 'gbagbọ s'oke. Ẹ ho iho ayọ gbogbo Séráfù, Fun ogun rere ti a fun wa Lat' ọwọ Mose Orimolade, T'o d'Ẹgbẹ Séráfù s'ayé. A ki yin gbogbo ẹyin oloye; Ẹ ku ajọdun oni yi, L'ọkunrin, l'obinrin, K'a se 'yi ka s'amọdun. Ẹ ho iho ayọ gbogbo Séráfù, Fun ogun rere ti a fun wa Lat'ọwọ Mose Orimọlade, T'o d'Ẹgbẹ Séráfù s'ayé. AMIN Ẹ ho iho ayọ gbogbo Séráfù, Fun ogun rere ti a fun wa Lat'ọwọ Mose Orimọlade, T'o d'Ẹgbẹ Séráfù s'ayé.
Hymn 707 – A KI yin e ku ajodun oni | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia