Hymn 706 – AWA l'omo ogun Kristi, Alleluyah | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "AWA l'omo ogun Kristi, Alleluyah" (C&S Hymn #706, Yoruba). AWA l'ọmọ ogun Kristi, Alleluyah, T'Oluwa gbe dide funra Rẹ…

Hymn 706 – AWA l'omo ogun Kristi, Alleluyah | C&S Yoruba Hymnary
AWA l'ọmọ ogun Kristi, Alleluyah, T'Oluwa gbe dide funra Rẹ Awa n sajọdun loni Alleluyah A dupẹ fun 'dasi ẹmi wa. Damuso ọmọ-Ogun Kristi, Kọrin soke s'Ọba wa, Ọpẹ ni fun Olugbala Alleluyah, Fun idasi wa d'ọjọ oni. Gbogbo Ẹgbẹ Kaduna, Alleluyah, Ẹ f'ogo fun Baba wa l' oke, F'Ẹgbẹ ọmọ-Ogun Kristi, Alleluyah, T'Oluwa gbe dide larin yin. Damuso ọmọ-Ogun Kristi, Kọrin soke s'Ọba wa, Ọpẹ ni fun Olugbala Alleluyah, Fun idasi wa d'ọjọ oni. Esu ma gbogun titi, Alleluyah, Lati b'ẹgbẹ Mimọ yi subu, Sugbọn Jesu gbe wa ro, Alleluyah, Ogo ni fun Baba wa loke. Damuso ọmọ-Ogun Kristi, Kọrin soke s'Ọba wa, Ọpẹ ni fun Olugbala Alleluyah, Fun idasi wa d'ọjọ oni. Ọpẹ f'Olugbala wa, Alleluyah, T'o da wa si lati esi wa, Awa si n gbadura, Alleluyah, K'a le se ọpọlọpọ ọdun. Damuso ọmọ-Ogun Kristi, Kọrin soke s'Ọba wa, Ọpẹ ni fun Olugbala Alleluyah, Fun idasi wa d'ọjọ oni. Jesu Olor' ẹgbẹ wa, Alleluyah,, A f'ogo f'orukọ Mimọ Rẹ; Jọwọ di wa l'amure, Alleluyah, K'a le jagun b'ọmọgun toto. Damuso ọmọ-Ogun Kristi, Kọrin soke s'Ọba wa, Ọpẹ ni fun Olugbala Alleluyah, Fun idasi wa d'ọjọ oni. Ki gbogbo ẹgbẹ ho ye, Alleluyah, K'a f'ogo fun Baba wa l'oke, K'a f'ogo fun Ọmọ Rẹ, K'a tun f'ogo fun Ẹmi Mimọ . Damuso Ọmọ-Ogun Kristi, Kọrin soke s'Ọba wa, Ọpẹ ni fun Olugbala Alleluyah, Fun idasi wa d'ọjọ oni. AMIN Damuso Ọmọ-Ogun Kristi, Kọrin soke s'Ọba wa, Ọpẹ ni fun Olugbala Alleluyah, Fun idasi wa d'ọjọ oni.

Hymn 706 – AWA l'omo ogun Kristi, Alleluyah | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia