Hymn 708 – BABA Orun wa gb'ope wa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "BABA Orun wa gb'ope wa" (C&S Hymn #708, Yoruba). BABA Ọrun wa gb'ọpẹ wa , Fun ajọdun wa oni yi, Fun idasi at'abo Rẹ,…
BABA Ọrun wa gb'ọpẹ wa , Fun ajọdun wa oni yi, Fun idasi at'abo Rẹ, T'o n fun wa lojojumọ. Jehofa Jire, Ran ibukun Rẹ si wa, K'awa le se'fẹ Rẹ d'opin Ko wa de Paradise. Olugbala wa gb'ọpẹ wa, T'isẹgun t'o n se fun wa, 'Gba t'esu n fẹ bi wa subu, Ti a si n ri 'ranwọ Rẹ. Jehofa Jire, Ran ibukun Rẹ si wa, K'awa le se'fẹ Rẹ d'opin Ko wa de Paradise. Kérúbù ati Séráfù, Ẹ jẹ k'a yin Baba wa, Ti ko f'ẹmi adaba Rẹ, Fun ẹranko igbẹ jẹ. Jehofa Jire, Ran ibukun Rẹ si wa, K'awa le se'fẹ Rẹ d'opin Ko wa de Paradise. Jehofa Shammah mbẹ wa, T'o ran Maikaeli si wa, Fun 'sẹgun wa l'ọna gbogbo Iyin fun Mẹtalọkan. Jehofa Jire, Ran ibukun Rẹ si wa, K'awa le se'fẹ Rẹ d'opin Ko wa de Paradise. Olupese wa y'o pese, Pese 'sẹ rere fun wa, Awọn agan y'o bimọ, Ẹni t'o bi a tunla. Jehofa Jire, Ran ibukun Rẹ si wa, K'awa le se'fẹ Rẹ d'opin Ko wa de Paradise. Wa pẹlu Ẹgbẹ Idalẹ, Kérúbù oun Séráfù, Pese fun wọn l'ọna gbogbo, Baba wa ba wọn 'sẹgun. Jehofa Jire, Ran ibukun Rẹ si wa, K'awa le se'fẹ Rẹ d'opin Ko wa de Paradise. A mbẹbẹ f'awọn ẹda Rẹ, T'o wa ni gbogbo ayé, K'a ronu pa iwa wa da, K'a le yẹ 'bugbe ọrun. Jehofa Jire, Ran ibukun Rẹ si wa, K'awa le se'fẹ Rẹ d'opin Ko wa de Paradise. Gbogbo ẹyin ero mimọ, Ti Ẹgbẹ Aladura, Ẹ se ra yin l'ọkansoso, Gẹgẹ bi Mẹtalọkan. Jehofa Jire, Ran ibukun Rẹ si wa, K'awa le se'fẹ Rẹ d'opin Ko wa de Paradise. Orin Halle, Halleluyah, Ni awa y'o kọ l'ọrun, Nigba t'a ba de'tẹ Baba, N'ile isura Ọrun. Jehofa Jire, Ran ibukun Rẹ si wa, K'awa le se 'fẹ Rẹ d'opin Ko wa de Paradise. AMIN Jehofa Jire, Ran ibukun Rẹ si wa, K'awa le se 'fẹ Rẹ d'opin Ko wa de Paradise.
Hymn 708 – BABA Orun wa gb'ope wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia