Hymn 698 – F'AWON eniyan Re to lo sinmi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "F'AWON eniyan Re to lo sinmi" (C&S Hymn #698, Yoruba). F'AWỌN eniyan Rẹ to lọ sinmi Awọn ti o f'igbagbọ jẹwọ Rẹ, A yin…
F'AWỌN eniyan Rẹ to lọ sinmi Awọn ti o f'igbagbọ jẹwọ Rẹ, A yin orukọ Rẹ, Olugbala, Halleluya! Iwọ l'apata wọn at'odi wọn, Iwọ ni Balogun wọn l'oju ja Iwọ ni imọlẹ okunkun wọn , Halleluya! Jẹ ki awọn ọmọ-ogun Rẹ layé, Jagun nitotọ b'awọn ti 'gbani, Ki wọn le gba ade ogo bi wọn, Halleluya! Idapọ ibukun wo lo to yi! Awa n ja nihin, awọn n yọ lọhun! Bẹ Tirẹ kan naa l'awa at'awọn. Halleluya! Gba t'ija ba n gbona ti ogun nle, A dabi ẹni n gborin ayọ wọn, Igboya a si de at'agbara, Halleluya! Ọjọ n lọ, orun wa fẹrẹ wọ na, Awọn ajagun toto y'o sinmi, Didun ni isinmi Paradise, Halleluya! Lẹhin eyi ọjọ ayọ kan mbọ, Awọn mimọ yoo jinde ninu Ogo, Ọba ogo y'o si wa larin wọn. Halleluya! Lat' opin ile lat' opin okun, Ogunlọgọ n ro wo 'bode Pearli; Wọn yin Baba, Ọmọ ati Ẹmi. Halleluya! Amin
Hymn 698 – F'AWON eniyan Re to lo sinmi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia